Loading...

Download
  • Genre:World Music/Folklore
  • Year of Release:2001

Lyrics

Solid foundation

Solid foundation


Iberu Oluwa ni ipinlese ogbon

Eniba f'Oluwa bere to f'Oluwa saaju

Lo kole sori apata

Ile ti a ko sori iyanrin

A ba yanrin lo

Micho Ade

Mo bere aye pelu iberu Olorun

Mo bere ise mi pelu iberu Olorun

Aye mi wa dabi ile ti a ko

Ise mi wa dabi ile ti a ko

Ti a ko sori apata to duro gbonin-gbonin


Ipinlese to dara ni yo fa opin to dara

Mase se tan koto roo ,koma baa dabamo

Ronu nipa ojo ola ohun too fee se

Solid foundation


Baba lo ranmi nise si gbogbo omo Nigeria

E teti kegbo

Edumare lo ranmi nise si gbogbo omo africa

E teti kegbo


Pupo ninu wahala ode-oni lojepe

Opo ninu wahala ode-oni lojepe

Asise ojo kan latowo awon baba nla wa

Tab'asise ojo kan latowo awon iya nla wa

Lat'ojo pipe

Eewo idile kan tabi eewo ilu

Asa idile tabi taaso dasa ibile

Egun idile tabi epe idile

Egun ilu tabi epe ilu

Oriki idile tabi tilu ati beebee lo

Seb'ori enikan loti bere

Koto dohun atiran-diran mofe kemo


Iyen nipe , akoba tab'asise ojo kan

Oleedi wahala aimoye odun

Asise eeyan kan,

O leedi wahala aimoye eniyan

Anfani eeyan kan

O leedi'gbadun egbegberun aimoye eniyan

Toriinaa, mase setan koto roo, koma baa dabamo

Ronu nipa ojo ola ohun too fee se

Solid foundation


Awon igbese aironu-jinle

Opo leti ribi to yorisi

Bibeeyan dasepo ati didowopo aironu-jinle

Igbeyawo aironu-jinle

Eto iselu aironu-jinle

Eto isakoso aironu-jinle

Ibere ore aironu-jinle

Ibere ote aironu-jinle

Koda, ibere ija aironujile

Opolopo leti ribi to yorisi


Gege bi apeere, isopo nigeria ni 1914

Iyen ni amagamation

E wa wo bi to yorisi

Ija oselu nile liberia ati ti seria-leone

Ija esin nile Algeria

S'eranti adehun Afonja,

Afonja ilorin belu Alimi Fulani

E wo ibere ajosepo Ife ati Moda'eke

Ibere ajosepo Olu.ikere at'ogoga

Fifagile ni 1993ati beebee lo

Sebi gbogbo e leti ribi to yorisi

Abamo kamase, asetan o daapon


Torinaa, mase setan koto roo koma ba dabamo

Ronu nipa ojo ola ohun toofee se

Solid foundation


Mase sohunkohun lairobiti yo yorisi

Iwe adehun lofee towo bo

Ronu ibiti yo yorisi

Koda bo jadehun enu lofe beniyan se

Ronu ibiti yo yorisi

Koto beniyan sore tabi kegbe po

Ronu ibiti yo yorisi

Kooto gbani sile tabi gbani sise

Ronu ibiti yo yorisi

Imoran lofee gbani tab'ejo lo fe da

Ronu ibiti yo yorisi

Ija ibinu lofee beniyan ja

Ronu ibiti yo yorisi

Oro ibinu lofe so jade

Ronu ibiti yo yorisi

Oro asiri lofee so feeyan kan

Ronu ibiti yo yorisi

Ipade ote ni won pe e si

Ronu ibiti yo yorisi

Ero tabi igbese nla kan lo fe gbe

Ronu ibiti yo yorisi

Olugbowo tabi oniduro lofee se feeyan

Ronu ibiti yo yorisi

Ohunkohun yowu tobaa fee se

Ronu ibiti yo yorisi

O baa ronu ibiti yorisi kooto dawole

Solid foundation

+

      -   or   -

      -   or   -

      NG +234
          -You can log in via below methods-
          Reset password via e-mail
          -or-
          Reset password via e-mail
          If you have any questions, please feedback on Boomplay App or send an email to [email protected].

          Please Select A Playlist

          Add New Playlist

          Share on

          Embed: Love & Light EP

          Custom Size :

          • Default
          • Desktop(300*600)
          • Mobile(300*250)

          Type :

          • HTML/HTML5 (WordPress Supported)
          Get Boomplay Premium
          for
          Payment Method
          Pay With
            Review and pay
            Order Date
            Payment Method
            Due Today
            Flutterwave
              Subscription Successful

              Congratulations! You have successfully activated Boomplay 1 Month Premium.

              Now you have access to all the features of Boomplay App.
              Payment Failed

              Please check your balance and then try again.

              You'll lose your subscription if we don't have a working payment method for your account, so please check your payment details.
              Need help? Contact Boomplay Subscription Support.
              Payment Processing...
              10 s

              Payment is being processed by . Please wait while the order is being comfirmed.

              Payment Processing
              Your order is processing, and it may take up to a few days for the service provider to handle your payment. Please kindly stay tuned and check your order status in ‘User Center’.
              About Order Status