![Ibowo Fagba](https://source.boomplaymusic.com/group10/M00/03/18/4ffe6dd1633148099631c0d98098624d_464_464.jpg)
Ibowo Fagba Lyrics
- Genre:World Music/Folklore
- Year of Release:2015
Lyrics
O se pataki nile Yoruba
Lati maa teriba fagbalagba
Lati maa bowo fawon agba
Atawon asaju rere
Kamaa bola fun won
Kamaa bowo fun won
O tun ba ofin Olorun mu
O se pataki nile Yoruba
Lati ma teriba f'agbalagba
Lati ma bowo fawon agba
Atawon asaju rere
Kamaa bola fun won
Kamaa bowo fun won
O tun ba ofin Olorun mu
Toripe, ohun tagbalagba ri lori ijoko
Bomode ba gungi kole ri
Ani, ohun tagbalagba ri lori ijoko
Bomode ba gungi kole ri
Atipe, bomode ba ngegi ninu igbo
Awon agba amoye, won a maa foye wole
Won maa wo'bi tigi ma wosi
Isinwewe toba foju d'arugidigba
Owo apeja lomaa bosi
Micho Ade, bomode baa laso bi agba
Kole lakisa t'agba
B'omode ba laso bi agba
Kole lakisa t'agba
Aifowo, fagba, koje kaye o roju
Aifagba fenikan koje kaye o tura
Aifowo fagba, koje kaye o roju
Aifagba fenikan koje kayeo tura
Eniyan le goke agba laitapa s'agbalagba
Eniyan le debo giga laidite m'awon asaaju
Eniyan le goke agba laitapa s'agbalagba
Eniyan le debo giga laidite m'awon asaaju
Gbogbo odo iwoyi, e baa rorase
Kama fagba seyeye, tor'agba nbowa kanni
Torinaa, mase bawon huwa ibaje tori ola
Sejeje baye ba n ye e
Sejeje oo, baye ba ntura a
Ma ma bawon huwa ibaje tor'aye le
Micho Ade, won bimi nile ogbon
Mo momi ogbon
Won bimi nile imo, mo f'omi oye we
Eyin agba e gbami o, mio f'oju diyin
Bewure ba wole ikooko, oju e a ja
Ewure toba wole ikooko, oju e a ja
Monamona loloogun legbe
Begbeji gbe paramole, yio tika benu
Fife la f'ado, ti a nfeje pa lara
Akengbe toje baba e, omi lafi npon
Mariwo toyo lasan, to nleri igbo
Ogomo toje baba e, a jepe o ndanu ni
Torinaa, mase bawon huwa ibaje, ola kiipe
Sejeje baye ba nye e
Sejeje baye ba ntura a
Ma ma bawon huwa ibaje tor'aye le