![Feyikogbon](https://source.boomplaymusic.com/group10/M00/03/18/4ffe6dd1633148099631c0d98098624d_464_464.jpg)
Feyikogbon Lyrics
- Genre:World Music/Folklore
- Year of Release:2015
Lyrics
Orin mi toteyi
Feyikogbon
Orin Micho-Ade
Feyikogbon ni
Odu mi toteyi
Feyikogbon
Haa
Feyikogbon ni
Omugo eniyan, komo pohun topo a maa tan
A wa domo alapata ti njeegun eran
Won sowa domo alaso ti nsagbe aloku aso
Omo elepo ti nsagbe epo
Omo onina ti nrin lokunkun
Awon eni abaata kafi ratupa, won wa soraawon dajitannawo
Bi wonse nsomo bi eru, bee na nsagba bi ewe
Kaluku wa nrin tifura ti fura, ni ilu abinibi eni
E dakun ki la o ti seyi si e so funwa
Orin mi toteyi
Feyikogbon, feyikogbon ni
Odu mi toteyi
Feyikogbon, feyikogbon ni
Eyin Omo Akin ti won dalaamu, nitori eto Omo eniyan
Mo kii yin, e ku iroju, e si ku afarada
Owe agbalagba ni, won ni eni teegun ba nle, koma roju, bose nrara-aye, bee lo nr' ara-orun
Sugbon ke kuku yago fawon Adan, tioseku, tioseye
Afomo koni gbongbo, gbogbo igi ni nbaatan
Awon kannaa lagbehinbeboje
Sebi taba npeniyan lole, koye ikotun maa fomo ewure sere
O dowo re, o dowo mi o, o dowo gbogbo wa
Orin mi toteyi
Feyikogbon, feyikogbon ni
Odu mi toteyi
Feyikogbon, feyikogbon ni
Orin Micho-Ade
Feyikogbon, feyikogbon ni
A l'odu mi toteyi o
Feyikogbon
Orin Micho-Ade
Feyikogbon ni