![Orin Ogo](https://source.boomplaymusic.com/group10/M00/12/22/17aff0f49847429291fd221cfe2f98bd_464_464.jpg)
Orin Ogo Lyrics
- Genre:Spirituals
- Year of Release:2021
Lyrics
Orin Ogo - Yinka Ayefele
...
Oluwa ni apata wa, laya Re l’awa yo sa si
Ohun kohun t’o wu ko de, Abo ninu iji ‘ponju,
Jesu li Apata f’awon alare, Fun alare, fun alare, Jesu li Apata f’awon alare, Abo ninu iji ‘ponju
Ko su wa lati ma ko orin ti igbani, Ogo f’olorun Aleluya
Awa yo fi igbagbo korin na s’oke kikan,Ogo f’olorun, Aleluya!
Omo olorun ni eto lati ma bu s’ayo, Pe ona yi nye wa si, Okan wa ns’aferi Re
Nigb’o se a o de afin Oba wa ologo,Ogo f’olorun, Aleluya!
Eje k’a f’inu didun, Yin Oluwa Olore
Anu Re O wa titi Lododo dajudaju, lododo dajudaju
Gbogbo aye, gbe Jesu ga, Angeli e wole fun, Emu ade oba re wa, Se l’oba, l’oba, l’oba, l’oba awon oba.
A bale pe l’awon t’orun, Lati ma juba re. K’a bale jo jumo korin, Se l’oba, l’oba, l’oba, l’oba awon oba.
E mi ‘ba n’egberun ahon,Fun ‘yin Olugbala
Ogo Olorun Oba mi, Isegun Ore Re.
Jesu t’o seru wa d’ayo, T’o mu banuje tan
Orin ni l’eti elese, Iye at’ilera.
E wole f’oba, Ologo julo,
E korin ipa ati ife Re, Alabo wa ni at’eni igbani
O ngbe ‘nu ogo, Eleru ni iyin
E so t’ipa Re, e so t’ore Re, ‘mole l’aso Re, gobi Re orun
Ara ti nsan ni keke ‘binu Re je
Ipa ona Re ni a ko si le mo
E yo ninu Oluwa, E yo, Eyin t’okan re se dede
Eyin t’o ti yan Oluwa, L’ibanuje ati aro lo. E yo, e yo, Eyo ninu oluwa e yo x2
Ogo ni f'Oluwa t'o se ohun nla, Ife lo mu k'O fun wa ni omo re
Eni t'o f' emi re lele f'ese wa, To si Ilekun iye sile fun wa.
Yin Oluwa, Yin Oluwa, Fiyin fun Oluwa
Yin Oluwa, Yin Oluwa, E yo niwaju re
K'a to Baba wa lo l'oruko Jesu, Jek'a jo f'ogo fun onise 'yanu
A f’ope f’olorun, L’okan ati l’ohun wa
Eni s’ohun ‘yanu, N’nu eni t’araye nyo
‘gbat’a wa l’om’owo, On na l’o ntoju wa
O si nf’ebun ife, Se ‘toju wa sibe.
K’a f’iyin on ope, F’Olorun, Baba, Omo
Ati Emi mimo, Ti O ga julo lorun
Olorun kan laelae, T’aye at’orun mbo
Be l’o wa d’isiyi, Beni y’o wa laelae.
Mimo, mimo,mimo, Olodumare
Ni kutukutu n’iwo yo gbo orin wa
Mimo, mimo, mimo ! Oniyonu julo
Ologo meta, lae Olubukun
Enikan mbe t’ O feran wa, A! O fe wa!
Ife Re ju ti yekan lo, A! O fe wa!
Ore aiye nko wa sile, B’ oni dun ola le koro,
Sugbon ore yi ko ntanni, A! O fe wa!
Okan mi yo ninu Oluwa tori O je’ye fun mi
Ohun Re dun pupo lati gbo, Adun ni lati r’oju Re, Emi nyo ninu Re, Emi nyo ninu Re
Gba gbogbo loun fi ayo kun okan mi
‘Tori pe oje iye funmi
IGBAGBO mi nwo O, Iwo Od’-agutan,
Olugbala, Jo gbo adua mi, M’ese mi gbogbo lo, K’emi lat’oni lo, Si je Tire.
‘Gba mo rin l’ okunkun, Ninu’ ibinuje
S’ amona mi, M’ okunkun lo loni,
Pa ‘banuje mi re, Lai, ma je ki nsako, Li odo Re.
Igbagbo mi duro lori, Eje atododo Jesu
N'ko je gbekele ohun kan, Leyin oruko nla Jesu
Modurole Krist’apata Ilemiran’ yanrin ni x2
Ha! Egbe mi, e w’ asia, Bi ti nfe lele!
Ogun ‘ jesu ferede na, A fere segun!
A fere segun, D’odi mu, Emi fere de, Beni Jesu nwi,
Ran ‘dahun pada s’ orun pe, Awa yo dimu!
Nipa ife olugbala, ki yio si nkan
Ojurere re ki pada, ki yio si nkan
Owon l'eje t'owo wa san, Pipe ledidi or'ofe
Agbara l'owo t'ogba ni, Kole si nkan
Bi a wa ninu iponju, ki yio si nkan
Igbala kikun ni tiwa, ki yio si nkan
Igbekele olorun dun, gbigbe ninu Kristi l'ere
Emi sin so wa di mimo, Kole si nkan
BABA to da orun meje, Ati ‘le meje pelu Aiye lo se ekedogun, Iyin ni f’oruko Re. Ijinle loro na, Awamaridi si ni x2
Mo ti ni Jesu lore, O j'ohun gbogbo fun mi
Oun nikan larewa ti okan mi fe
Oun n'Itanna Ipado, Irawo Owuro
Oun nikan l'Arewa ti okan mi fe
Olutunu mi lo je ni gbogbo wahala
Oun ni ki n kaniyan mi l'Oun lori
Oun n'Itanna Ipado, Irawo Owuro
Oun nikan l'Arewa ti okan mi fe
Laifoya lapa Jesu, Laifoya laya Re
Labe ojiji 'fe Re, Lokan mi yo sinmi x2
Ha! Ipile ti jesu fi le’le l’eyi, Ti Baba, Aladura nto,
K’eda mase ro pe, O ye kuro nibe, O duro le Krist‘ apata.
Eyo! Kerubu E yo, Serafu Eyo,
A fi pile lele lori otito, A fi pile lele Lori ododo
B'aiye mbu Mose, Awon Angeli nfe
Olorun Abraham nfe, Awon Ogun Orun si ngbadura re, Olorun Metalokan Kerubu Eyo Serafu Eyo,A fi pile lele lori otito, A fi pile lele lori ododo.
Wa ba mi gbe, ale fere le tan, Okunkun nsu, Oluwa ba mi gbe; Bi oluranlowo miran ba ye, Iranwo alaini, wa ba mi gbe
Mo nfe O ri, ni wakati gbogbo
Kilo le segun, esu b’ore Re?
Tal’o le se amona mi bi re?
N’nu ‘banuje at’ayo wa ba mi gbe
Ma toju mi, Jehofah nla,
Ero l' aiye osi yi, Emi ko l' okun, iwo ni,
F' ow' agbara di mi mu, Ounje orun x2
Ma bo mi titi lailai x 2
Lo kede ayo na fun gbogbo aiye
P'Omo Olorun segun iku
Fi tiyin-tiyin pel'ayo rohin na, P’ Omo olorun jinde
Oba mi de , Asegun mi de
Ogo, iyin, ola at'agbara at'pa
F'Odaguntan to gunwa
DURO, duro fun Jesu,Enyin om’ogun Krist’:
Gbe asia Re s’ oke,A ko gbodo fe ku;
Lat’ isegun de ‘segun,N’ y’o ma to ogun Re
Ti ao segun gbogb’ ota,Ti Krist’ y’o jOluwa.
Duro, duro fun Jesu,F’ eti s’ ohun ipe;
Jade lo s’ oju ija, L’ oni ojo nla Re;
Enyin akin ti nja fun, Larin ainiy’ ota
N’nu ewu e ni ‘gboiya, Dojuko agbara.
O FUN mi l’ edidi, ‘Gbese nla ti mo je;
BO ti fun mi, Osi rerin, Pe Mase gbegbe mi
Ki tun s’ edidi mo, Sugbon iranti ni! Pe gbogbo igbese mi ni, Emmanueli san