Mo Mope Mi Wa Lyrics
- Genre:Afrobeats
- Year of Release:2012
Lyrics
Oba to ku nitori mi oba ta pa nitori ese mi
Oba ta kan nitori mi mo mope mi wa fun o
Oba to ku nitori mi oba ta pa nitori ese mi
Oba ta kan nitori mi mo mope mi wa fun o
A da lebi’ku ke mi le gba idalare
A nan i pasan ke mi ma ba ji ya
O ti kikan to mu kin ma je koro ni
A tu to si lara ke mi le deni apole
Ikoro irora to je nitoori temi ni
Oba to ku nitori mi oba ta pa nitori ese mi
Oba ta kan nitori mi mo mope mi wa fun o
Lailai yi je bi ese a si da lebi ese
Iso owo ati ese re pelu opo egbere iya ese mi ni
Ori ogo lo fi dade e e egun fun mi
Emi o mo oun ti mo ja mo o to fi se gbogbo iwon yi
Mo mope wa fun oba to seyi funmi
Oba to ku nitori mi oba ta pa nitori ese mi
Oba ta kan nitori mi mo mope mi wa fun o
Odo aguntan ko k’ese mi lo oloore to gba mi la o
Ope anu to po yi mi o rire mo wa pelu emi imore
Oba to dala yi ni ke mi le do loro
Mo mope wa fun oo baba
Oba to ku nitori mi oba ta pa nitori ese mi
Oba ta kan nitori mi mo mope mi wa fun o
Iwo lo jeko pari ise ati iya to to simi
Iwo lo je ko tan aisan ati arun ti un ba ri
Iwo lo gba kokoro iku ati sa iboji ti mi ba wo
Oba to ra iye fun mi emi mope wa o oshey
Oba to ku nitori mi oba ta pa nitori ese mi
Oba ta kan nitori mi mo mope mi wa fun o
Odo aguntan to ke se mi lo to so mi do oo re
Mo mope mi wa fun o oshey
Oba aiyeraye to fi ite re sile wa jiya fun emi
Mo mope mi wa fun o modupe
Owo elese un oba orun ko le da duro
Mo mope mi wa fun o
Oro aiyeraye to deru nitori temi
Mo mope mi wa fun o
Iya to je lona agbelebu ma ni gbagbe ni mo mo
Mo mope mi wa fun o
Oba to laiye to lorun to wa da layi lara
Mo mope mi wa fun o modupe
Obo ogo re kale o waiye waa gbe ese mi wo o
Mo mope mi wa fun o
Oro isura ogo iyebiye lo fi fun mi logun je
Mo mope mi wa fun o
Iku e lori iji Calvary i lofi ra iye fun emi o
Mo mope mi wa fun o
Ori ade aiyeraye lofi de tegun nitori mi
Mo mope mi wa fun o modupe
Emi mo riri ajinde re kemi ma ba se gbe ni
Mo mope mi wa fun o
Ore ofe ti mo rigba lai ni yele lo jen mope wa
Mo mope mi wa fun o
Oun gbogbo to se to se fun mi
Mo mope mi wa fun o modupe
Bi mo legberun ahan ko to yin o o ipinle ese
Mo mope mi wa fun o modupe
Alase pe igbagbo olurapada ore toto
Mo mope mi wa fun o modupe
Mo mope mi wa feni to fe mi lati odo inu e
Mo mope mi wa fun o
Oba to feran mi ju enikeni lo o
Mo mope mi wa fun o modupe
Ore ayiri olutan okan mi mo gbope ore de
Mo mope mi wa fun o
Ope ni mo wa da o ope ni wa du
Mo mope mi wa fun o