
Maje Koro Mi Sun e Lyrics
- Genre:Traditional
- Year of Release:1979
Lyrics
Maje Koro Mi Sun e - C.A.C Good Woman Choir, Ibadan. Led By Mrs D.A Fasoyin
...
Iwo ti s'orisun Ayo, bami setemi Iwo ti s'orisun ayo, bami se kankan Má jẹ́ kọ́rọ̀ mi su ọ ò baba rere /2x
Ìwọ ni ẹni tí mo lè sá wá bá
Ìwọ ni agbọ̀rọ̀dùn ọmọ òrukàn
Gbà mí baba, mámà jẹ́ kọ́rọ̀ mi ó sú ọ
Òrùlé b'àjà mọ́'lẹ̀, awọ fẹ́lẹ́ bo'nú kò jẹ́ a ríkùn aṣeni
Lójú aṣebi, bíi káràjò kámá se démọ́
Lojú ọ̀dàlẹ̀, bíi ká k'ẹ́rù tà san gbèsè
Ayé ló ṣe'la, ila fi ko lori
Aye lo s'ekan, ikan wewu eje
K'aye ma pa kadara mi da no se sa was
Esin laye mo baba ma je n sesin
Gba mi baba, iwo apata igbala mi
Bami se temi o jare baba rere
Iwo ti s'orisun Ayo, bami setemi Iwo ti s'orisun ayo, bami se kankan Má jẹ́ kọ́rọ̀ mi su ọ ò baba rere /2x
……
Awon kan ti sa di o, o segun fun won
Tete d'emi ba lohun baba rere
Awon kan to gbe o lori, o dawon lare
Tete gbemi na leke aronipin
Mo tiro titi baba owo mi ko ma t'eti
Mo naga ga ga sine ori mi ko ma d'oke
Gbami baba lowo awon amoniseni
Gbami baba lowo asenibanidaro
Mo yun le ifa, oro mi ko ma yanju
Mo sogun sogun, ota mi ko ma dehin
Omi to n gbe mi lese lo ko dori ekun
Gbami baba, ma ma je k'odo aye gbe mi lo
Se ranwo mi like erupe k'ota ma yomi
Iwo in olugbala, Iwo lo le gbami
Maje koro mi su o o baba rere
Igba meta lo wa nigba eda laye, k'ale ko san mi j'owuro baba rere/2x
Iwo in alagbawi eda gbogbo
Gba temi wi baba je n se rere
Ki n riba tise, ki n rona gbe GBA
Je k'aye mi dara k'igba mi ko sunwon
Ma je n sin won waye, ma ma joro mi o ja sofo.