
Jesu Lona Otito Lyrics
- Genre:Traditional
- Year of Release:1979
Lyrics
Jesu Lona Otito - C.A.C Good Woman Choir, Ibadan. Led By Mrs D.A Fasoyin
...
Chorus: Jesu wipe oun Lona otito (2x)
odore ni mo gba wole Baba
kohun aye mase de mi Lona, nijoba Baba mi.
kin le ba Jesu mi joba,
Solo 1 -Jesu olugbala iwo lona otito
emi o tele oo Baba mi ore mi
larin idanwo atiji aye maro moo dopin
tori nile ti ojo kii sha, ilu Olorun wa, ilu elewa a ni, tikosi banuje, ojare Baba mumi de be.
Chorus: Jesu wipe oun Lona otito (2x)
odore ni mo gba wole Baba
kohun aye mase de mi Lona, nijoba Baba mi.
kin le ba Jesu mi joba.
Solo 2 - Ni ilu Olorun wa, aise dede kosi nibe,
ko soju to lomije, kosi pinya tabi nira, fun awon ta ti dariji, o jare Baba mumi debe.
ekun ki yo si lorun bee ni ailera koni si, gbogbo ilu na je imole, awon Angeli tosan toru won ko Halleluya si Baba, mimo, ogo, ola seni metalokan, orin iyin lao mako si Odoagutan ti apa, o jare Baba mumi debe.
Chorus: Jesu wipe oun Lona otito (2x)
odore ni mo gba wole Baba
kohun aye mase de mi Lona, nijoba Baba mi.
kin le ba Jesu mi joba.
Solo 3 - Irobinuje kosi lorun, beni kosi si imi edun, akii soro kikoro, oro ayo lao magbo latenu Baba Agba, bi ibanuje wa lokan tori ipinya timbe, sugbon ayo lao ma yo loke lodo Baba wa, o jare Baba mumi debe.
Chorus: Jesu wipe oun Lona otito (2x)
odore ni mo gba wole Baba
kohun aye mase de mi Lona, nijoba Baba mi.
kin le ba Jesu mi joba.
Solo 4 - 'Gbati pe Oluwa badun, taye yo si fo lo, timole ojo titun ba si de, taba n poruko lorun, kamiye Baba kamiye nijobaa re, o jare Baba mumi debe.
Chorus: Jesu wipe oun Lona otito (2x)
odore ni mo gba wole Baba
kohun aye mase de mi Lona, nijoba Baba mi.
kin le ba Jesu mi joba.
Solo 5 - Lojo na tawon oku ninu Kristi yo ji dide, ti won yo si pin ninu ogo ajinde tawon ayanfe, kamiye Baba kamiye nijobaa re, o jare Baba mumi debe.
Chorus: Jesu wipe oun Lona otito (2x)
odore ni mo gba wole Baba
kohun aye mase de mi Lona, nijoba Baba mi.
kin le ba Jesu mi joba.
Call &Resp:
Solo: Ijoba egberun odun
Resp:Kinle ba Jesu mi joba
Solo: Ati taye raye
Resp: Kinle ba Jesu mi joba
Solo: Nibi ti ko sekun
Resp: Kinle ba Jesu mi joba
Solo: Ara n nimi kosi
Resp: Kinle ba Jesu mi joba
Solo: Gberumi somi kosi
Resp: Kinle ba Jesu mi joba
Solo: Ogun ota kosi
Resp: Kinle ba Jesu mi joba
Solo: Ayo ni titi
Resp: Kinle ba Jesu mi joba
Solo: Mumi debe Baba
Resp: Kinle ba Jesu mi joba
Solo: Olorun ayeraye
Resp: Kinle ba Jesu mi joba
Solo: Nile re loke ooo
Resp: Kinle ba Jesu mi joba
Solo: Mumi debe Baba rere, moke pe o, dakun Baba, Baba gbami, Alagbawi eda.
Chorus: Jesu wipe oun Lona otito (2x)
odore ni mo gba wole Baba
kohun aye mase de mi Lona, nijoba Baba mi.
kin le ba Jesu mi joba.