
Olufunke Lyrics
- Genre:Others
- Year of Release:2022
Lyrics
Hmmmnnn
Olúfúnkẹ́
Gbogbo ìwà pálapàla tọ n wù yí ò mọ̀ dáa
Ah mummy, ẹ ẹ̀ já rárá
Àwa Slay Mama l'eléyí
Ha ha ha ha ha
It's IdeBBo oh oh oh
Olúfúnkẹ́ ọmọ ìyá ẹlẹ́kọ
Olúfúnkẹ́ arẹwà omidan
Wọ́n bá ẹ wí n'ílé
O bá ẹsẹ̀ rẹ s'ọ̀rọ̀, o sálọ n'ílé eh eh
Ta ló n tàn ẹ́ gangan
Ṣ'awọn bọda àdúgbò ló n kó sí ẹ lórí (Ah! Ó mà ṣe)
Olúfúnkẹ́ ẹ ẹ
Ah, ò bá má ì lọ
Ayé gb'ẹgẹ́ ẹ ẹ́
Ò bá dúró ko gb'èkọ́
To bá lọ l'óyún pẹ́rẹ́n, ahhh
Career ẹ bàjẹ́ nìyẹn
See, àwọn boys, ẹnu wọn dùn o
They are just deceiving you irọ́ ni
Tẹ́'ti ẹ ko gbọ́ mi yé o o o Fúnkẹ́, nitori,
Ìyà ní ó pọ̀ f'ọ́mo tí ò gbọ́ràn
Ìyà ní ó jẹ, yíò j'ewé iyá o
Iyà ọ̀la n bọ̀ f'ọ́mọ tí ò gbọ́ àmọ̀ràn o
Yó gé 'ka àbámọ̀ o
Mo ni, iyà ní ó pọ̀ f'ọ́mo tí ò gbọ́ràn
Ìyà ní ó jẹ, yíò j'ewé iyá o
Ìyà ọ̀la n bọ̀ o, f'ọ́mọ tí ò gbọ́ àmọ̀ràn o
Yó gé 'ka àbámọ̀
Olúfúnkẹ́
Àrùn mà pọ̀ l'óde
Àwọn tó n f'ọmọ ṣ'owó
Wọ́n pọ̀ n Ṣàngó òde
O ní boyfriend mẹ́jọ o
O tún lo ní sugar daddy mẹ́fà
O wá fi n yangàn l'óde o, Olúfúnkẹ́
O ló n ṣ'ayẹ́
Òbí ẹ n kìlọ̀ fún ẹ ò, ayé n tàn ẹ́
O lọ n tàn candle
O jẹ́ lọ ṣọ́ra ọ̀rẹ́ mi ò, o jẹ́ ṣe pẹ̀lẹ́
Ko má bàá di example, nítori
Ìyà ní ó pọ̀ f'ọ́mo tí ò gbọ́ràn
Ìyà ní ó jẹ, yíò j'ewé iyá
Iyà ọ̀la n bọ̀ f'ọ́mọ tí ò gbọ́ àmọ̀ràn o
Yó gé 'ka àbámọ̀ o
Mo ni, iyà ní ó pọ̀ f'ọ́mo tí ò gbọ́ràn
Ìyà ní ó jẹ, yíò j'ewé iyá o
Iyà ọ̀la n bọ̀ o, f'ọ́mọ tí ò gbọ́ àmọ̀ràn o
Yó gé 'ka àbámọ̀
Óyá ẹ bá mi kìlọ̀ f'Olúfunkẹ́ o (janjan kò gbọ́ràn janjan)
Ẹ kìlọ̀ f'Olúfunkẹ́ (janjan kò gbọ́ràn janjan)
Kó má bàá k'ábámọ̀ láyé o
Kán má fi ṣe example ìyà l'áyé
Ẹni a wí fún ọba jẹ́ o gbọ́
Ẹni a kìlọ̀ fún ọba òkè jẹ́ ó gbà torí
Ikún j'ọgẹ̀dẹ̀ ikún rè'dí mọ́'lẹ̀
Ikún ò tètè mọ̀ p'óhun tó dùn ló n pani o
Orí ọ̀kẹ́rẹ́ koko l'áwo o
B'a wi f'ọ́mọ ẹni a gbọ́
Janjan janjan janjan janjan jan
Koko janjan
Koko janjan janjan janjan janjan jan eh eh