Ma Ronu Mo Lyrics
- Genre:Gospel
- Year of Release:2001
Lyrics
Omo eniyan kilode tironu gbaye
Kila o je, Kila o mu nironu aye
Omo eniyan kilode tironu gbaye
Kila o je, Kila o mu nironu aye
Kini ironu re
Se atije ni tabi atimu oh
Olorun ti o pese feye oju orun
Olorun ti o pese feja inu ibu
Olorun ti n pese fun gbogbo eranko igbe yo pese
Nitori awon omo kiniun ni salaini
Ebi a si ma pawon kakiri
Sugbon awon ti o fe oluwa
Ki yo salaini oun rere oh
Nitori na wa gbo ohun alore
O n ke oh, wipe ki o ma ronu mo oh
Ohun alore
Ohun alore e
Oni pa ironu ti
Ma boluwa rin oh
Oun tironu o lese
Igbagbo lese oh
Omo eniyan
Gbo oh, Ma ronu mo
Bawo la o se sise
Ironu kan niyen
Ninu aye
Ise sise ko seyin olorun, fokan re bale oh
Oluwa lo mona abayo, ma ronu mo
Se ati sise ni ibanuje re
Boya oti jade lati bi odun mefa
Oti gbekele eniyan fun ise re
Egbe ni fun eniyan to feleran ara se igbekele re
Nitori na gbekele olorun iyanu
Boya oti gbekele awon egbon re ti n be ni eko
Abi awon egbon re ti n be ni abuja
Won ja o kule to wa n sokun kaakiri oh
To ba le gbekele olorun alaye
Wo oh, yi o pese ise re oh
Gbo ohun eleda re
Oni ko ba n rin ninu igbagbo ninu odun yi
Iyanu yo sele oh loju ona re oh
Ohun alore
Ohun alore e
Oni pa ironu ti
Ma boluwa rin oh
Oun tironu o lese
Igbagbo lese oh
Omo eniyan
Gbo oh, Ma ronu mo
Pele oh arabinrin
Se ireti ti pin lori oro re oh
O ti pa ironu ti kia kia
Ki o tele olorun alaye oh
Se nitori aiti loko tabi aiti bimo ni
Arakunrin, wa gbo ohun eleda re oh
Se aiti rise, tabi aiti laya
Gbekele olorun alaye
Nitori ekun ko le gba o
Nu oju re nu oh, ki o gbagbo oh
Nitori, oluwa olorun agbaye ni o se eda re
Eleda re kole fi o sile oh ki o ma jiya
Gbogbo ironu re ni, seni ki o fiti si ara olorun oga ogo
Yi o se iyanu
Oodi olomo, oodi alaya, oodi oloko oh
Ohun alore
Ohun alore e
Oni pa ironu ti
Ma boluwa rin oh
Oun tironu o lese
Igbagbo lese oh
Omo eniyan
Gbo oh, Ma ronu mo