![Iwo Ni Mo Ni Olorun](https://source.boomplaymusic.com/group1/M00/01/29/rBEeMlfx8QKADX4PAAB8Ma4vQIE362.jpg)
Iwo Ni Mo Ni Olorun Lyrics
- Genre:Afrobeats
- Year of Release:2012
Lyrics
Iwo Ni Mo Ni Olorun - Baba Ara
...
Iwo ni mo o mo, iwo ni moo ni oo
Iwo ni mo o no, iwo ni moo ni oo
Haaa Oluwa, ma fimi sile leekan
Iwo ni moo mo, iwo ni moo ni ooo
Iwo ni mo ni o iwo ni mo mo
Iwo ni moo mo, iwo ni moo ni ooo
Haaa Oluwa, ma fimi sile leekan
Gbogbo ohun, gbogbo ogbon, gbogbo ogo at'odo re ni
Gbogbo ohun, gbogbo ogbon, gbogbo ogo at'odo re ni o
Ma fimi sile leekan
Gbeega, Ooloore, gbee Jesu ga, Olorun ayo mi
E bami gbe Baba ga ooo
Gbeega, Ooloore, gbee Jesu ga, Olorun ayo mi
Ife lo fi wa mi ri laiwo ese mi
O gbe mi s'ejika re pada bo wa s'agbo
O gbo pe mo fere ku o tu ororo si
O so fun mi jeje pe t'oun ni emi
Nko gbohun to dun bi eyi ri l'okan mi se nyo oo
Gbeega, Ooloore, gbee Jesu ga, Olorun ayo mi
(Beat interlude)
E bami yin Baba ooo, e bami yin Baba ooo,
Oba to nlo mi oo, fun ogo re nikan
Oba to nlo mi oo, fun ogo re nikan
Me mo lee p'ore Baba mo'ra
E je ka f'inu didun, yin Oluwa Oloore,
Aanu re o wa titii, l'ododo dajudaju, l'ododo dajudaju (2ce)
B'onimu ba ngbe'mu, b'elegan ba npegan, Jesu ni ma sin nitemi o eee.......ahhhhhh ehhhhh
B'onimu ba ngbe'mu, b'elegan ba npegan, Jesu ni ma sin d'ale o eee......ahhhhhh ehhhhh
Jesu ni Baba mi, oun lo ni mi, oun lo da mi
Oun lo nlo mi, fun ogo re
(Interlude)
Me mo ni r'arinnu laye mi ooooooe
Arinnu, arinnu ke, me mo ni r'arinnu laye mi
Olugbala mo ni jawo mi
Eyin Baba mo ni mo pon si o ee eee
Abiyamo lo lomo, olomo lo n'igbaja
Abiyamo o ni gb'omo juule ko gbe langidi pon o
Abiyamo o ni gbo'gbe omo re ko ma ta'ti kiji oo
Emi mo ni r'arinnu nitemi oo eeee eeo
Arinnu, arinnu ke, me mo ni r'arinnu laye mi
Olugbala mo ni jawo mi
Eyin Baba mo ni mo pon si o ee eee
Lat'origun mereerin agbaye, ran alaanu simi oo
Lat'origun mereerin agbaye, ran alaanu simi oo
Je nrin b'alaanu pade, je k'omo eda saanu mi
Eja nla saanu Jonah o gbe s'ebute
Baba mimo saanu Hannah o so d'olomo
Baba mimo saanu Mose o gbe Mose n'ija oo
Baba mimo saanu aye o, o ran Jesu w'aye
Jesu Kristi saanu Lasaru, o s'oku d'alaaye oo
Ko soro fun o lati saanu mi, alaanu julo saanu mi
E mo soro fun o lati saanu mi, alaanu julo saanu mi
Baba mimo...Baba mimo ma gbagbe mi
Baba mimo ooo, Baba mimo ma gbagbe mi
Ori mi ma gbagbe adehun ta jo se, eda mi ma gbagbe oro ta jo so
Baba mimo oo, Baba mimo ma gbagbe mi
Baba mimo ooo, Baba mimo ma gbagbe mi
Ori mi ma gbagbe adehun ta jo se, eda mi ma gbagbe oro ta jo so
Mo ti b'ori mi so oo, wipe maa lowo løwø
Wipe maa bi'mo le'mo o, wipe maa r'ona gbe temi gba o, wipe ona mi a la si rere,
Wipe ona mi a la s'ohun to dara, ori mi mømø gbagbe o Baba rere
Baba mimo, Baba mimo ma gbagbe mi
Baba mimo oo, Baba mimo ma gbagbe mi
Ori mi ma gbagbe adehun ta jo se, eda mi ma gbagbe oro ta jo so
K'ologun de k'ologun maa lo
K'ologun de k'ologun maa bo o, me mø ni ja nitemi o, tori mo ti l'Olugbeja kan ninu Baba
Won a dabi iyangbe niwaju afefe, awon ti ngbogun ti ni Olorun ri'se won
Awon ti nba ni ja yi Olorun ri'se won
Amo Olorun l'abo mi ati agbara, lowolowo iranlowo nigba iponju ni
Tori naa emi ki yio beru o, bi a tile si aye n'idi
Ti a si awon oke nla nipo lo si okun
Oluwa awon omo ogun wa pelu awa o
Olorun Jakobu ni aabo wa
K'ologun de k'ologun maa lo
K'ologun de k'ologun maa bo oo
Me mo ni ja nitemi o, tori mo ti l'olugbeja kan ninu Baba...Jesu Kristi lee je
B'oso lo f'owo kan mi oran lo ma da o
Aje lo f'owo kan mi egbe lo maa se
Mo ti duro ti Jesu mi oro ana ma ko oo
Mo ti gboju, mo ti gboya, mo ti d'alagbara
Eni ba fe so bee ko ma ni Baba o
Oniyan ø fe so bee ko yaa sunmo Baba
Ko duro ti Jesu re pelu awe at'adura o
Ko yø'wø ninu ese, ko d'olowo funfun
B'oso ba f'owo kan mi oran lo ma da o,
Aje lo f'owo kan mi egbe lo maa se,
Mo ti duro ti Jesu mi oro ana ma ko o
Mo ti gboju, mo ti gboya, mo ti d'alagbara
Babaaaa, ngo maa pe eee, ngo p'olongo re f'eniyan gbogbo
Baba orun, ngo maa pe eee, ngo p'olongo re f'orile-ede gbogbo
Se mi l'ayanfe re, se mi l'ayanfe re titi lai
Se mi l'ayanfe re, se mi l'ayanfe re titi lai... jøø o, jøø o,
Se mi l'ayanfe re, k'emi le sin o d'opin titi lai
Baba orun, ngo maa pe eee, ngo p'olongo re f'eniyan gbogbo
Babaaa, ngo maa pe eee, ngo p'olongo re f'eniyan gbogbo
Se mi l'ayanfe re, se mi l'ayanfe re titi lai
Se mi l'ayanfe re, se mi l'ayanfe re titi lai...jøø o, jøø o
Se mi l'ayanfe re, k'emi le sin o d'opin titi lai
Se mi l'ayanfe re, Se mi l'ayanfe re
Se mi l'ayanfe re titi lai