Kin Se Laini Reti / K' awa Elese Lyrics
- Genre:Gospel
- Year of Release:2020
Lyrics
Kin Se Laini Reti / K' awa Elese - Emmanuel Somuyiwa
...
Ki ‘se l’aini ‘reti
Ni mo to ‘wa
Ki’se laini’gbagbo
Ni mo kunle,
Ese ti g’ ori mi
Eyi sa l’ebe mi,
Eyi sa l’ebe mi,
Jesu ti ku.
A! Ese mi po ju,
O pon koka
Ada le, ada le
Ni mo nd’ese;
Ese aiferan Re
Ese aigba O gbo,
Ese aigbo O gbo,
Ese nlanla.
Oluwa, mo jewo
Ese nla mi,
'O mo bi mo ti ri,
Bi mo ti wa;
Jo, we ese mi nu,
K’okan mi mo loni,
K’okan mi mo loni,
Ki ndi mimo.
Olododo ni O,
O ndariji
L’ese agbelebu
Ni mo wole;
Jek’eje iwenu
Eje od’agutan,
Eje od’agutan,
We okan mi.
‘Gbana alafia
Y’o d’okan mi,
‘Gbana uno ba O rin,
Ore airi;
Em’ o f’ara ti O;
Jo ma to mi s'ona,
Jo ma to mi s’ona,
Titi aye.
Amin.