- Genre:Traditional
- Year of Release:2021
This song is not currently available in your region.
Try the alternative versions below.
Alternative versions:
Lyrics
Ojo - Beautiful Nubia
...
Òjò, òjò, a mú’lé tutù
Òjò, a mú’lẹ̀ fọ’hùn
T’ọmọdé t’àgbà l’ó nṣ’àdúrà k’ójò ayọ̀ rọ̀ lé wọn l’órí
T’akọ t’abo l’ó nṣ’àdúrà k’ójò ayọ̀ rọ̀ lé wọn l’órí
Ọ̀rẹ́ gbé’ra n’ílẹ̀, mú’ra ká bọ́ s’ọ́nà
Ìgboyà la ó fi bo’rí òkùnkùn biri
Àìní àti ìf̀asẹ́yìn kò le mú wa mọ́’lẹ̀ mọ́ o
Ẹ̀rùn yí d’ópin, ìdẹ̀ra nbọ̀ wá o
Ayọ̀ nbọ̀ l’ọ́nà - ìnira wọ gbó, ìrọ̀rùn yíò wá d’onílé
Ẹ̀rọ̀ nbọ̀ wá o - ìgbà ọ̀tun ti dé f’ẹ́ni tí ò mi’kàn
Ọ̀rẹ́ gbé’ra n’ílẹ̀, k’á f’ọwọ́ so’wọ́ pọ̀
Oun tó nbẹ n’ílẹ̀ yí kìí ṣ’iṣẹ́ àdáṣe
K’á má ṣe bí ẹni nf’ẹnu rò’fọ́ t’ébi á pa sùn
Jọ̀wọ́ gb’áradì, ìṣẹ́gun nbọ̀ l’ọ́nà
Ògo nbọ̀ l’ọ́nà - àìlera wọ gbó, ìrọ̀rùn yíò wá d’oníle
Ẹ̀rọ̀ nbọ̀ wá o - ìgbà ọ̀tun ti dé f’ẹ́ni tí ò mi’kàn
T’a bá wo b’ó ṣe rí ọ̀rẹ́ o
Ó dàbí kò le tò mọ́
Sùgbọ́n a ó dìde pẹ̀lú inú kan
Òmínira wa nbọ̀!