
Jesu Oro Re Ye Lyrics
- Genre:Gospel
- Year of Release:2020
This song is not currently available in your region.
Lyrics
Jesu Oro Re Ye - Bode Afolabi
...
1. JESU, ọrọ Rẹ ye
O si ntọ ṣiṣẹ wa
Ẹnit' o ba gbagbọ
Y'o l'ayọ on 'mọle.
2. Nigba' ọta sunmọ wa
Ọrọ Rẹ l'odi wa
Ọrọ itunu ni
Ìkọ igbala ni.
3. B'igbi at'okunkun
Tilẹ bo wa mọlẹ
Mọlẹ re y'o to wa
Y'o si dabobo wa.
4. Tani le so ayọ
T'o le ka isura
Ti ọrọ Rẹ nfi fun
Ọkan onirẹlẹ?
5. Ọrọ anu, o nfi
Lera fun alaye
Ọrọ iye, o nfi
Itunu f'eni nku.
6. Awa iba le mọ
Ẹkọ ti o nkọni
Ki a ba le fe Ọ
K'a si le sunmọ Ọ. Amin