
ELESE MO NFE ‘BUKUN Lyrics
- Genre:Spirituals
- Year of Release:2020
This song is not currently available in your region.
Lyrics
ELESE MO NFE ‘BUKUN - Temidayo Oladehin
...
1. ẸLẸSẸ mo nfẹ 'bukun
Onde: mo nfẹ d'omnira
Alare: mo nfẹ simi
"Ọlọrun, sanu fun mi."
2. Ire kan emi ko ni
Ẹsẹ sa l'o yi mi ka
Eyi nikan l'ẹbẹ mi
"Ọlọrun, sanu fun mi."
3. Irobinuje ọkan!
Nko gbọdọ gboju s'oke
Iwọ sa mọ̀ ẹdun mi
"Ọlọrun, sanu fun mi."
4. Ọkan ẹsẹ mi yi nfẹ
Sa wa simi laiya rẹ
Lat'oni, mo di Tirẹ
"Ọlọrun, sanu fun mi."
5. Ẹnikan mbẹ l'or itẹ
Ninu Rẹ nikansoso
N'ireti at'ẹbẹ mi
"Ọlọrun, sanu fun mi.”
6. On o gba ọran mi ro
On ni Alagbawi mi
Nitori Tirẹ nikan
"Ọlọrun, sanu fun mi." Amin