Yin Oluwa ft. Conastone Lyrics
- Genre:Gospel
- Year of Release:2024
Lyrics
Èmi ó yìn ọ́
Olúwa Ọlọ́run mi
Emi o yin o
Pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi
Èmi ó yìn ọ́
Olúwa Ọlọ́run mi
Èmi ó fògo f'orúkọ rẹ títí láé láé
Èmi ó yìn ọ́
Olúwa Ọlọ́run mi
Èmi o yin ó
Pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi
Gbogbo ọkàn mi
Óyá jí dìde ko yin olúwa o
Èmi ó fògo f'orúkọ rẹ títí láé láé
Ẹ lọ s'énu ọ̀na rẹ̀ ti ẹ̀yin ti ọpẹ́ o
Torí opẹ́ loúnjẹ rẹ
Orin opẹ́ ní ma kọ
Oba kankan tí kò pẹ́ méjì
Kì kì dá opẹ́ ni mo mú wá
Kì kì dá opẹ́ kì kì dáa wurà
Adé ògo lo de
Bí àgbọ̀nrí ṣe n mí hẹlẹ sí ipádò omi
Beè lọkàn mi lón mi hẹlẹ sí ọ
Gbogbo ohun tí mo ní l'áyé l'ọ́run tìre ni
Gbogbo soprano aọto tenor mi ni ma fi gbé o ga
Èmi ó yìn ọ́
Olúwa Ọlọ́run mi
Emi o yin o
Pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi
Ẹ lọ s'ẹ́nu ọ̀na rẹ̀
Ti ẹ̀yin ti ọ́pẹ o
(Àti sí àgbàla rẹ̀) èmi ó fògo f'orúkọ rẹ títí láé láé
Èmi ó yìn ọ́
Títí ẹ̀mí mi yó fi pin
Èmi o yin ó
Pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi
Eni tí a sẹ lóore tí ò dúpẹ́
Bí ọlọ́ṣà akóni lẹ́rù lọ ni
Èmi ó fògo f'orúkọ rẹ títí láé láé
Bí ẹni bá mo inú rò ámọpẹ́ dá
Mo wá rírì fún ọba ògo
Oba tó gbé tálákà sókè látinú ẹrùpẹ̀ wá
Kò s'óhun tí kò lẹ̀ ṣe adáni má gbàgbé
Olórúkọ ńlá ọba ńlá má yo ọwọ́ re láraà mi
Èmi ti rí isẹ́ ọwọ́ rẹ lára òkun
Mo ti rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ láara ọ̀sà
Ọba à ńsá yá tí kìń sá
Ọlọ́run májẹ̀mú òdodo
Òkè ńlá arógun mámà fọ́
Kàbìtì kabiti eee
Èmi ó yìn ọ́
Olúwa Ọlọ́run mi
Emi o yin o
Pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi
Gbogbo ọkàn mi
Jí gìrì gbéra ṣà ṣà dìde
Ko yin olúwa oooo
Èmi ó fògo f'orúkọ rẹ títí láé láé
Ìwo to ní gbogbo ògo
Tó ni ayé ní ìkáwọ́ oṣẹ́ o
Emi o yin o
Pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi;
Títí ẹ̀mí mi yó fi pin
Ni ó ma f'ògo fún ọ ooooo
Èmi ó fògo f'orúkọ rẹ títí láé láé
Kábiọ́òsí mo wá rìrì níwájúù rẹ
Èmi ó yìn ọ́ (Èmi ó yìn ọ́ ooooo)
Gbogbo ọkàn mi yó yin ọ́ oo
Kòsí ǹkan tí mo fẹ́ fi kun
Èmi ó fògo f'orúkọ rẹ títí láé láé
Yin Olúwa ìwọ ọkàn mi
Yin olúwa yin ọlọ́ruǹ mi
Yin Olúwa ìwọ ọkàn mi
Mo mí wárìrì níwájú ọba adánimágbàgbé
Yin Olúwa ìwọ ọkàn mi
Ẹ lọ sí ẹnu ọ̀na rẹ̀
Àti sí àgbàláa rẹ̀ k'ẹmáa dúpẹ́ fun k'ẹmáa fi ìbùkún fun
Yin Olúwa ìwọ ọkàn mi
Mímọ́ mímọ́ l'àwọn ọ̀run ńké l'àwọn ayé ńké
Orúkọ rẹ̀ mímọ́
Yin Olúwa ìwọ ọkàn mi
Kòsí ibìkan tàbí èdè kan t'a ò ti gbọ́ ìróo wọn
Ìróo wọn la gbogbo ayé já
Yin Olúwa ìwọ ọkàn mi
Óní ẹ máa yin olúwa
Kẹ f'ìbùkún fún orúkọ rẹ̀
F'ìbùkún fún olúwa ọkàn mo
Kín le majẹ́ tìrẹ nìkan laílaí