FI IYIN FUN JESU OLURAPADA Lyrics
- Genre:Gospel
- Year of Release:2024
Lyrics
FI IYIN FUN JESU OLURAPADA - OLUWALONIBISI
...
1. Fi iyin fun Jesu, Olurapada wa,
Ki aye k' okiki ife Re nla,
Fi iyin fun! Eyin Angeli ologo,
F'ola at'ogo fun oruko Re
B'Olus'agutan, Jesu y'o to Omo Re,
L'apa Re l'o ngbe won le l'ojojo;
Eyin eniyan mimo ti ngb'oke Sion;
Fi iyin fun pelu orin ayo
2. Fi iyin fun, Jesu Olurapda wa,
Fun wa, O t'eje Re sile, O ku,
On ni apata, ati reti 'gbala wa,
Yin Jesu ti a kan m'agbalebu;
Olugbala t'O f'ara da irora nla,
Ti a fi ade egun de l'ori,
Eniti a pa nitori awa eda
Oba ogo njoba titi laelae
3. Fi iyin fun, Jesu Olurapada wa
Ki ariwo iyin gba orun kan,
Jesu Oluwa njoba lae ati laelae,
Se l'Oba gbogb' eyin alagbara;
A segun iku; fi ayo royin na ka,
Isegun re ha da, isa oku?
Jesu ye ko tun si wahala fun wa mo
'Tori O l'agbara lati gbala